Expand your communication

We are so pleased to share with you that our Language of the Month series is returning with a range of events, online content and interviews to inspire you. Let us release the linguist in you as we discover the plethora of Languages on offer at Morley!

Our October Languages of the Month are Yoruba and Patois. Be inspired to release the linguist in you with these student testimonials reflecting on expanding their communication with loved ones…  

Orúkọ mi ni Muminah, mo ń gbé ní ìlu Scotland. Ọ̀dọ́bìnrin ogún ọdún ni mi, mo jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ní Edinburgh Yunifásítì. Lọ́jọ́ iwájú, mo fẹ́ di onímọ̀ sáyẹ́ǹsì Mo bẹ̀rẹ̀ẹ  kíláàsí yìí ni ọdún tó kọjá. Mo  fẹ́ kọ́ Èdè Yorùbá nítorí pé, mo fẹ́ láti sọ̀rọ̀ ni Yorùbá pẹ̀lú ebí mi àti lọ́jọ́ iwájú, mo fẹ́ láti kọ́ ọmọ mi ní  èdè Yorùbá. Nísinsìnyí, mo lè sọ Yorùbá diẹ sìí. Mo gbádùnun kíláàsí yìí nítorí pé ẹ̀kọ́ wa ìmóríyá gbáà ló jẹ́ àti wípé onírẹ̀lẹ̀ àti aláwàdà ènìyàn ni olùkọ́ wa.

My name is Muminah, I live in Scotland. I’m a 20-year-old young woman, I’m a student at Edinburgh University. In the future I would like to become a scientist

I started this class last year, I wanted to learn Yoruba because I want to be able to speak in Yoruba with my family and in the future, I want to be able to teach my children Yoruba. Now, I can speak more Yoruba. I enjoy this class because our lessons are fun and our teacher is a nice, humble and funny person.

Muminah Koleoso

Orúkọ mi ni. Abísọ́lá.  Mo ń gbé ní ìlu London. Mo jẹ́ òǹkọ̀wé. Mo bẹ̀rẹ̀ẹ kíláàsí yìí ni ọdún tó kọjá. Mo wá kọ́ èdè Yorùbá nítorí wípé. Mo fẹ lati mu dara si agbara sisọrọ mi.

Mo rí àṅfàní nínu ẹ̀kọ́ yìí nítorí wípé mo ti ko pupo. Lára àwọn ẹ̀kọ́ tí mo kọ́, tí mo fẹ́ sọ nípa ni ìmọ́tọ́tọ́ àti ìlera ara ẹni àti ìlànà ìṣe ojojúmọ.

My name is Abisola. I live in London. I work as a Medical Writer. I started this course last year. I wanted to learn Yoruba because I wanted to improve my speaking ability. This course has benefited me because I have learned a lot. Amongst the topics we covered is personal health and hygiene and daily routine

Abisola Akinbowale

Orúkọ mi ni Khalif Koleoso Mo ń gbé ní ìlu Glasgow.  Mo ńṣe  iṣẹ́ ayàwòrán fún àwọn akọ́lé (àwọ́n tí ó ń kọ́ ilé). Mo bẹ̀rẹ̀ẹ kíláàsí yìí ni ọdún tó kọjá. Ìdí tí mo fi wa kọ́ èdè Yorùbá ni wípé  mo fẹ́ sọ èdè awọ́n ẹbí mi dada .  Ẹ̀kọ́ yìí ṣe mí ní àṅfàní púpọ̀. Mo dúpẹ́ wípé mo ní àṅfàní àti gbìyànjú láti máa sọ Yorùbá dáadáa . Ó jẹ́kí n lè máa kọ́ àwọn ọ̀rọ̀ tuntun. Ẹ̀kó oríṣiríṣi ni mo kọ́ bíi ẹ̀yà ara, oríṣiríṣi iṣẹ́, àbùdá ara àti ìwà ènìyàn, ìgbà/àsìkò, àròkọ lẹ́tà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àṅfàní gan an ni èdè Yorùbá jẹ́. 

My name is Khalif Koleoso I live in Glasgow. By profession, I work as an architectural assistant. I started this class last year, I wanted to learn Yoruba because I want to better speak the language of my family. 

This cause has been very beneficial. I have also learnt a lot about different things in Yorùba to do with body parts, physical characteristics and personality traits, seasons, letter writing, weather etc. This has added to my vocabulary and has benefited me a lot. I am getting more confident in the language. I have received real benefit in that. For this, I am very grateful. Thank you. 

Khalif Koleoso 

Orùkọ́  mi ni Motúnráy Mo ń gbé ní ìlu London. Mo jẹ́ olùṣàkóso akoonu oní- nọ́mbà. Mo bẹ̀rẹ̀ẹ kọ́lẹ̀jì yìí ni ọdún meji sẹ́hin. Mo fẹ́ kọ́ èdè Yorùbá nítorí pé, mo fẹ́ láti má sọ̀rọ̀ ní Yorùbá pẹ̀lú ebí mi àti kin lè ma sọọ́ tààrà. Mo feran kíláàsí yìí gan nítorí ẹ̀kọ́ yìí gbadùn, a ní àṅfàní láti bá ara wa sọ̀rọ̀ lọ́pọ̀lọ́pọ̀. Wọ́n ṣe ètò ẹ̀kọ́ yìí dáradára. 

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀kọ́ ni mo kọ́ nínú ẹ̀kọ́ yìí, bíi àwọn ọ̀rọ̀ ìṣe, àwọn ohun ojoojúmọ́, ìgbà/àsìkò/àkókò, ṣíṣàpèjúwe ènìyàn, ibìkán àti nṅkan, ìsimi olófin/aláìlófin, àròkọ́ lẹ́tà, ìmọ́tótó àti ìléra ara àti pàtàkì rẹ̀ ní àsìkó àjàkálẹ́ àrún in Kòrónà, oríṣiríṣi iṣẹ́, ọ̀nà èdè, àwọ̀, ọjọ́ inú ọ̀sẹ̀, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Nínú àwọn ẹ̀kọ́ tí á kọ́ ni ṣíṣàpèjúwe àbùdá ara àti ìwà ènìyàn. Ènìyàn gíga ni mí. Mo ga tó ẹsẹ̀ bàtà márùnún àti íǹsì mọ́kànlá. Mo mọ́ra díẹ̀. Adáraya ènìyàn ni mí. Ìṣe ìdánilẹ́kọ̀, ìrànlọ́wọ́ àti ìwúriI jẹ́ àwọn ṅkan tí mo nífẹ̀ẹ́ sí gidigidi láti máa ṣe. Yoùbá dùn ún sọ. Mo fẹ́ràn lati má kọ́ Yorùbá pelu olùkọ́ Ìdẹ̀ra ni Kọ́lẹ̀jì Morley.

My name is Motunrayo. I live in London. I work as a Digital Content Manager. I started this course 2years ago. I wanted to learn Yorùbá because I want to be able to speak it with my family and also to be able to speak it fluently . I like this course a lot because it is interractive, fun, well planned and put together.

I learnt a lot of things on this course such as verbs, daily objects, seasons, time, describing people, places and things, formal and informal holidays/ letter writing, health and hygiene and the importance during the pandermic (Corona Virus), different professions, figurative speech, colours, days of the week. The  list goes on.

Amongst the topic I’m able to present is describing physical characteristics and personality traits. I am 5 feet and 11 inches tall. I’m a bit light in complexion and very lively. Enjoying mentoring, assisting and encouraging people is my passion. Yoruba is a delight to speak. I truly enjoy learning with our tutor Ìdẹ̀ra at Morley college.

Motunrayo Sholola

A kúu déédé àsìkò yìí. Orúkọ mi ni Mustaphis Koleoso. Mo ń gbé ní ìlu Edinburgh ni Scotland ṣùgbọ́n mo wa láti ìlu Èkó ni Náìjíríà. Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ parí ẹ̀kọ́ gíga, mo ka ẹ̀kọ́ọ  chemical engineering Mo bẹ̀rẹ̀ẹ kílásì yìí ni ọdún tó kọja nítorí mofẹ́ ṣe ìdàgbàsókè nínú èdè yìí mo dẹ̀ fẹ́ fi sọ̀rọ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn tó ṅ sọ Yorùbá ni Nàìjíríà nígbà tí mo bá padà lọ sí ìlú mi. Mo rí àṅfàní nínú ẹ̀kọ́ yìí nígbà tí èmi àti àwọn ẹgbẹ́ mi à ṅ bára wa sọ̀rọ̀. 

Lára ẹ̀kọ́ tí mo kọ́ tí mo fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa ni àbùdá ara àti ìwà ènìyàn. Ènìyàn gíga ni mí. Mo níìrẹ̀lẹ̀ nígbà púpọ̀, mo dẹ̀ jẹ́ ènìyán aláwàdà púpọ̀ náà ṣùgbọ́n ní ìgbà ìmíì, mi kìí ní ìrẹ̀lẹ̀ rárá modẹ̀ má ṅ ṣe agídí díẹ̀. Mi ò ga púpọ̀, mo dúdú, modẹ̀ tírín. Mo gbádùn ẹ̀kọ́ yìí gan an, modẹ̀  fún ẹnikẹ́ni tóbá fẹ́ kọ́ èdè míì àt fún ẹni tóbá fẹ́ kọ̀ Àṣà Nàíjíríà àtí àwọn ènìyàn Yòrùbá. 

Compliments of the season. My name is Mustaphis Koleoso. I live in Edinburgh in Scotland I started this course last year. I just finished studying so I’m graduated at the university. I studied chemical engineering.I wanted to learn Yorùbá because I just want to be able to converse with our people back in Nigeria and I just want to improve my familiarity with language. This course is been quite beneficial to me because I’ve learnt a lot of things. I’ve learnt new vocabularies, I’ve learnt new ways to the structure of the language. 

Some of the things I’ve learnt and would like to talk about is physical characteristics and personality traits and how to speak about them in Yorùbá. I am a humble person, always but stubborn at times, funny, relaxed, not tall, slim and also dark in complexion

Mustaphis Koleoso.

A kúu déédé àsìkò yìí. Orúkọ mi ni Oreòfẹ̀   Mo ń gbé ní ìlu Milton Keynes. Mo ń  ṣiṣẹ́ fun ìjọba. Mo bẹ̀rẹ̀ẹ kíláàsì yìí ni ọdún tó kọjá. Mo fẹ́ kọ́ èdè Yorùbá nítorí wípé mo fẹ sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ìgboyà sí àwọn òbí mi. Mo rí àǹfàní nínú ẹ̀kọ́ yìí làti kọ́ èdè Yorùbá dára dára pẹ̀lu ọ̀rẹ́ tuntun. Olùkọ́ tó kọ́ mi gbọ́n gan, wọ́ń dẹ̀ ní sùúrù tó pọ̀ọ̀. Wọ́ń ṣe àbójútó ẹ̀kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lu sùúrù láti jẹ́ kí gbogbo wa ṣe àṣeyọrí yen papọ̀ọ̀. 

Compliments of the season. My name is Grace. I live in Milton Keynes. By profession, I work for the government. I started this course last year. I wanted to learn Yoruba because I wanted to speak it with confidence to my parents. This course has benefited me to learn Yoruba well and meet amazing new friends. My teacher is smart and is very kind. She cares about the learning of her students and makes sure they learn together.

Grace Egbewole – Adereti

Yoruba is one of Africa’s most widely spoken languages and is a good language to speak if you are thinking about travelling in West Africa. We have everything from taster sessions to intermediate courses so why not give it a go?